Deutarónómì 5:28-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Ọlọ́run ń gbọ́ nígbà tí ẹ̀yin ń bá mi sọ̀rọ̀ Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti gbọ́ ohun tí àwọn ènìyàn yí sọ fún ọ. Gbogbo ohun tí wọ́n sọ dára,

29. ìbá ti dára tó, bí ọkàn wọn bá lè bẹ̀rù mi, tí ó sì ń pa gbogbo òfin mi mọ́ nígbà gbogbo, kí ó bá à lè dára fún wọn, àti àwọn ọmọ wọn láéláé.

30. “Lọ sọ fún wọn kí wọn padà sínú àgọ́ wọn.

31. Ṣùgbọ́n ìwọ túbọ̀ dúró síbí pẹ̀lú mi, kí n bá à lè fún ọ ní àwọn àsẹ tí o gbọdọ̀ fi kọ́ wọn láti máa tẹ̀lé ní ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún wọn láti ní.”

Deutarónómì 5