Deutarónómì 4:42-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Níbi tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn le sálọ, bí ó bá ṣe pé ó ṣèèṣì pa aládúgbò rẹ̀ láìsí ìkùnsínú láàrin wọn. Òun le sálọ sí èyíkéyìí nínú ìlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, fún ìgbàlà ẹ̀mí ara rẹ̀.

43. Àwọn ìlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà nìwọ̀nyí: Bésérì ní òkè olórí títẹ́ tí ó wà ní aṣálẹ̀, fún àwọn ará Rúbẹ́nì; Rámótì ní Gílíádì fún àwọn ará Gádì àti Gólánì ní Básánì fún àwọn ará Mánásè.

44. Èyí ni òfin tí Mósè gbékalẹ̀ fún àwọn ará Ísírẹ́lì.

Deutarónómì 4