Deutarónómì 32:30-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún,tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbàaàrún sá,bí kò ṣe pé Àpáta wọn ti tà wọ́n,bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ?

31. Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí Àpáta wa,àní àwọn ọ̀ta wa tìkálára wọn ń ṣe onídàájọ́.

32. Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sódómùàti ti ìgbẹ́ ẹ Gòmórà.Èṣo àjàrà wọn kún fún oró,Ìdì wọn korò.

33. Ọtí wáìnì ni ìwọ ti dírágónì,àti oró mímú ti pamọ́lẹ̀.

34. “Èmi kò to èyí jọ ní ìpamọ́èmi kò sì fi èdìdì dìí ní ìṣúra à mi?

Deutarónómì 32