Deutarónómì 32:22-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú un mi,yóò sì jó dé ipò ikú ní ìṣàlẹ̀.Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.

23. “Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lóríèmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.

24. Èmi yóò mú wọn gbẹ,ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n.Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀.

25. Idà ní òde,àti ìpayà nínú ìyẹ̀wù.Ni yóò run ọmọkùnrin àti wúndíá,ọmọ ẹnu-ọmú àti arúgbó eléwù irun pẹ̀lú.

26. Mo ní èmi yóò tú wọn káèmi yóò sì mú ìrántí i wọn dà kúró nínú àwọn ènìyàn,

27. nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀ta,kí àwọn ọ̀ta a wọn kí ó mába à wí pé, ‘Ọwọ́ ọ wa lékè ni;kì í sì í ṣe Olúwa ni ó ṣe gbogbo èyí.’ ”

28. Wọ́n jẹ́ orílẹ̀ èdè tí kò ní ìmọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò sí òye nínú un wọn.

29. Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọnkí wọn ròbí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí!

Deutarónómì 32