1. Fetísílẹ̀, Ẹ̀yin ọ̀run, èmi yóò sọ̀rọ̀;ẹ gbọ́, ìwọ ayé, ọ̀rọ̀ ẹnu un mi.
2. Jẹ́kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò,kí awọn ọ̀rọ̀ mi máa ṣọ̀kalẹ̀ bí ìrì,bí òjò winiwini sára ewéko túntún,bí ọ̀wàrà òjò sára ohun ọ̀gbìn.
3. Èmi yóò kókìkí orúkọ Olúwa,Áà, ẹ yìn títóbi Ọlọ́run wa!
4. Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé,gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo.Ọlọ́run olótìítọ́ tí kò ṣe àsìṣe kan,Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun.
5. Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀;fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́,ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apákan tí ó sì doríkodò.
6. Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa,Áà ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn?Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín,tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín?