Deutarónómì 3:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. (Àwọn ará Sídónì ń pe Hámónì ní Sírónì: Àwọn Ámórì sì ń pè é ní Sénírì)

10. Gbogbo àwọn ìlú tí o wà ní orí òkè olórí títẹ́ náà ni a gbà àti gbogbo Gílíádì, àti gbogbo Báṣánì, títí dé Ṣálékà, àti Édíréì, ìlú àwọn ọba Ógù ní ilẹ̀ Báṣánì.

11. (Ógù tí í ṣe ọba Báṣánì nìkan ni ó ṣẹ́kù nínú àwọn ará Ráfátì. Ibùsùn rẹ̀ ni a fi irin ṣe, ó sì gùn ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́tàlá lọ ní gígùn àti ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà ní ìbú. Èyí sì wà ní Rábà ti àwọn Ámórì.)

Deutarónómì 3