Deutarónómì 24:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Rántí ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ṣe sí Míríámù lójú ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí o jáde kúrò ní Éjíbítì.

10. Nígbà tí o bá wín arákùnrin rẹ ní ohunkóhun, má ṣe lọ sí ilé rẹ̀ láti gba ohun tí ó bá mú wá bí ẹ̀rí.

11. Dúró síta gbangba kí o sì jẹ́ kí ọkùnrin tí o wín mú ògò rẹ jáde wá fún ọ.

Deutarónómì 24