3. Nígbà náà ni àwọn àgbààgbà ìlú tí ó wà nítòòsí òkú yóò mú ẹgbọ̀rọ̀ abo màlúù tí kò ì siṣẹ́ àti tí kò ì tíì fà sí àmì ìsìn ẹrú,
4. kí wọn sìn ín wá sí àfonífojì tí a kò ì tíì ro tàbí gbìn àti ibi tí odò ṣíṣàn wà. Níbẹ̀ ní àfonífojì wọn yóò kán ọrùn ẹgbọ̀rọ̀ màlúù.
5. Àwọn àlùfáà, ọmọ Léfì yóò wá ṣíwájú, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún un àti láti bùkún ní orúkọ Olúwa àti láti parí gbogbo ẹjọ́ àríyànjiyàn àti ọ̀rọ̀ ìlú.
6. Nígbà náà ni gbogbo àwọn àgbààgbà ìlú tí ó wà nítòsí yóò wẹ ọwọ́ wọn lórí ẹgbọrọ abo màlúù tí a ti kan ọrùn rẹ̀ ní àfonífojì,