Deutarónómì 16:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Kí a má ṣe rí ìwúkàrà ní ọ̀dọ̀ ọ yín nínú ilẹ̀ ẹ yín fún ọjọ́ méje. Ẹ má ṣe jẹ́ kí nǹkan kan sẹ́kù nínú ẹran tí ẹ ó fi rúbọ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní di àárọ̀ ọjọ́ kéjì.

5. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ìrékọjá náà ní ìlúkílùú kankan, tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín

6. bí kò ṣe ibi tí yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀, níbẹ̀ ni ki ẹ ti ṣe ìrúbọ ìrékọjá náà ní ìrọ̀lẹ́ nígbà tí òòrùn bá ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránti ìgbà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.

7. Ẹ ṣun ún kí ẹ sì jẹ ẹ́ ní ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn. Ní àárọ̀, kí ẹ padà sí àgọ́ ọ yín.

8. Ọjọ́ mẹ́fà ní kí ẹ fí jẹ àkàrà aláìwú, ní ọjọ́ kéje, ẹ pe àjọ kan fún Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan.

9. Ka ọ̀ṣẹ̀ méje láti ìgbà tí ẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà.

10. Nígbà náà ni kí ẹ se àjọ̀dún ọ̀ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, nípa pípèṣè ọrẹ àtinúwá, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín.

Deutarónómì 16