Deutarónómì 10:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Èmi yóò sì tún ọ̀rọ̀ tí ó wà lórí síléètì àkọ́kọ́ tí o fọ́ kọ sórí rẹ̀. Kí o sì fi wọ́n sínú àpótí náà.”

3. Mo sì kan àpótí náà pẹ̀lú igi kaṣíà, mo sì gbẹ́ síléètì òkúta méjì náà jáde bí i ti ìṣáájú. Mo sì gòkè lọ pẹ̀lú síléètì méjèèjì lọ́wọ́ mí.

4. Olúwa tún ohun tí ó ti kọ tẹ́lẹ̀ kọ sórí síléétì wọ̀nyí. Àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó ti sọ fún un yín lórí òkè, láàrin iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀. Olúwa sì fi wọ́n fún mi.

5. Mo sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, mo sì ki àwọn síléètì òkúta náà sínú àpótí tí mo ti kàn, bí Olúwa ti pàṣẹ fún mi, wọ́n sì wà níbẹ̀ di ìsinsin yìí.

Deutarónómì 10