Dáníẹ́lì 7:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. “Nígbà náà, ni mo fẹ́ mọ ìtúmọ̀ òtítọ̀ ẹranko kẹrin, tí ó yàtọ̀ sí àwọn yóòkù, èyí tí ó dẹ́rù ba ni gidigidi, tí ó ní eyín irin àti èékánná idẹ, ẹranko tí ó ń run tí ó sì ń pajẹ, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tó kù mọ́lẹ̀.

20. Bẹ́ẹ̀ ni mo sì fẹ́ mọ̀ nípa ìwo mẹ́wàá orí i rẹ̀ àti nípa ìwo yóòkù tí ó jáde, nínú èyí tí mẹ́ta lára wọn ṣubú, ìwo tí ó ní ojú, tí ẹnu rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ìgbératga.

21. Bí mo ṣe ń wò, ìwo yìí ń bá àwọn ènìyàn mímọ́ jagun, ó sì borí i wọn,

Dáníẹ́lì 7