1. Beliṣáṣárì, ọba ṣe àsè ńlá fún ẹgbẹ̀rún (1,000) kan nínú àwọn ọlọ́lá a rẹ̀, ó sì mu wáìnì pẹ̀lú u wọn.
2. Bí Beliṣáṣárì ṣe ń mu wáìnì, ó pàṣẹ pé kí wọn kó kọ́ọ̀bù wúrà àti ti fàdákà wá, èyí tí Nebukadinéṣárì bàbá rẹ̀ kó wá láti inú tẹ́ḿpìlì ní Jérúsálẹ́mù, kí ọba àti àwọn ọlọ́lá a rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀ kí ó ba à le fi mu wáìnì.