26. Bí wọ́n ṣe pàṣẹ pé kí wọn fi kùkùté àti gbòǹgbò igi náà sílẹ̀, èyí túmọ̀ sí wí pé a ó dá ìjọba rẹ padà fún ọ lẹ́yìn ìgbà tí o bá ti mọ̀ wí pé, Ọ̀run jọba.
27. Nítorí náà ọba, jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọ, kọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sílẹ̀ kí o sì ṣe rere, àti ìwà búburú rẹ nípa ṣíṣe àánú fún àwọn talákà. Ó lè jẹ́ pé nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe rere.”
28. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí Nebukadinéṣárì ọba.
29. Lẹ́yìn oṣù kejìla, bí ọba ṣe ń rìn káàkiri lórí òrùlé ààfin ìjọba Bábílónì,
30. Ó sọ pé, “Èyí ha kọ́ ni Bábílónì ńlá tí mo kọ́ gẹ́gẹ́ bí ilé ọba, nípa agbára à mi àti fún ògo ọláńlá à mi?”