Dáníẹ́lì 2:9-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Tí ẹ̀yin kò bá lè sọ àlá mi, ìjìyà kan ṣoṣo ló wà fún un yín. Ẹ̀yin ti gbèrò láti pa irọ́ àti láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ti ó lè ṣi ni lọ́nà fún mi, títí tí nǹkan yóò fi yí wọ́. Nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, èmi yóò sì mọ̀ pé ẹ lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi.”

10. Àwọn awòràwọ̀ sì dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ènìyàn kan ní ayé tí ó lè sọ nǹkan tí ọba béèrè! Kò sí ọba náà bí ó ti wù kí ó tóbi àti kí ó lágbára tó, tí í béèrè irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tàbí awòràwọ̀.

11. Nǹkan tí ọba béèrè yìí ṣòro púpọ̀. Kò sí ẹni tí ó lè fi han ọba à fi àwọn òrìṣà, tí wọn kì í gbé láàrin ènìyàn.”

12. Èyí mú kí ọba bínú, ó sì kanra, nítorí náà ó pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn amòye Bábílónì run.

13. Nítorí náà àṣẹ yìí jáde lọ wí pé kí a pa àwọn amòye, wọ́n ránṣẹ́ pe Dáníẹ́lì pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ láti pa wọ́n.

14. Nígbà tí Áríókù, olórí àwọn olùṣọ́ ọba, jáde láti lọ pa àwọn amòye Bábílónì, Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ fún un pẹ̀lú ọgbọ́n àti òye.

15. Ó béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùṣọ́ ọba wí pé, “Èéṣe tí àṣẹ ọba fi yá kánkán bẹ́ẹ̀?” Áríókù sì ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà fún Dáníẹ́lì.

16. Nígbà náà ni Dáníẹ́lì wọlé tọ ọba lọ, ó sì tọrọ kí ọba fún òun ní ààyè, òun yóò fi ìtumọ̀ àlá náà hàn fún ọba.

17. Nígbà náà ni Dáníẹ́lì padà lọ sí ilé e rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Hananíáyà, Míṣáẹ́lì àti Ásáríyà.

18. Ó sọ fún wọn pé kí wọn bèèrè fún àánú Ọlọ́run ọ̀run nípa àsírí náà, kí ọba má ba à pa àwọn run pẹ̀lú àwọn amòye Bábílónì.

19. Ní òru, àsírí náà hàn sí Dáníẹ́lì ní ojú ìran. Nígbà náà ni Dáníẹ́lì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run

20. Dáníẹ́lì wí pé:“Ọpẹ́ ni fún orúkọ Olúwa láé àti láéláé;tirẹ̀ ni ọgbọ́n àti agbára

21. Ó yí ìgbà àti àkókò padà;ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò.Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́nàti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye.

22. Ó fi ohun ìjìnlẹ̀ àti àsírí hàn;ó mọ ohun tí ó pamọ́ nínú òkùnkùnàti ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ wà

23. Mo dúpẹ́, mo sì fi ìyìn fún ọ, ìwọ Ọlọ́run àwọn baba mi:ó ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbáraó ti fi àwọn nǹkan tí a bèrè lọ́wọ́ rẹ̀ hàn fún minítorí tí ìwọ ti fi àlá ọba hàn wá.”

24. Nígbà náà ni Dáníẹ́lì títọ́ Áríókù lọ, ẹni tí ọba yàn láti pa àwọn amòye Bábílónì run, Dáníẹ́lì wí fún un pé, “Má ṣe pa àwọn amòye Bábílónì run. Mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, èmi yóò sí sọ ìtumọ̀ àlá rẹ̀ fún un.”

25. Lẹ́ṣẹ̀kan náà, Áríókù yára mú Dáníẹ́lì lọ sí iwájú ọba, ó sọ fún ọba pé, “Èmi ti rí ọkùnrin kan lára àwọn àjèjì tí ó wá láti Júdà, ẹni tí ó lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.”

26. Ọba béèrè lọ́wọ́ ọ Dáníẹ́lì ẹni tí a tún ń pè ní Beliteṣáṣárì pé, “Ṣé ìwọ lè sọ ohun tí mo rí nínú àlá mi àti ìtumọ̀ ọ rẹ̀ fún mi?”

27. Dáníẹ́lì dá ọba lóhùn pé, “Kò sí awòràwọ̀ kan, apògèdè, onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tí ó lè ṣe àlàyé àsírí tí ọba béèrè fún

28. ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àsírí hàn. Ó ti fi han ọba Nebukadinéṣárì, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ọjọ́. Àlá àti ìran tí o rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ ni ìwọ̀nyí:

29. “Ọba, bí ìwọ ṣe ṣùn sórí ibùsùn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ ń ro àwọn ohun tó ń bọ̀, olùfihàn àsírí ń fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ fún ọ.

Dáníẹ́lì 2