Àwọn Hébérù 9:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Àti lẹ́yìn aṣọ ìkelé kejì, òun ni àgọ́ tí à ń pè ní ibi mímọ́ jùlọ;

4. Tí ó ní àwo tùràrí wúrà, àti àpótí májẹ̀mú tí a fi wúrà bò yíká, nínú èyí tí ìkòkò wúrà tí ó ní mánà gbé wà, àti ọ̀pá Árónì tí o rúdí, àti àwọn wàláà májẹ̀mú;

5. Àti lórí rẹ̀ ni àwọn kérúbù ògo ti i ṣíji bo ìtẹ́ àánú; èyí tí a kò lè sọ̀rọ̀ rẹ̀ nísinsin yìí lọ́kọ̀ọ̀kan;

6. Ǹjẹ́ nígbà tí a ti ṣe ètò nǹkan wọ̀nyí báyìí, àwọn àlùfáà a máa lọ nígbàkúgbà sínú àgọ́ èkínní, wọn a máa ṣe iṣẹ́ ìsìn.

Àwọn Hébérù 9