Àwọn Hébérù 9:18-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nítorí náà ni a kò ṣe ya májẹ̀mú ìṣáájú páàpáà sí mímọ́ láìsí ẹ̀jẹ̀.

19. Nítorí nígbà tí Mósè ti sọ gbogbo àṣẹ nípa ti òfin fún gbogbo àwọn ènìyàn, ó mú ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù àti ti ewúrẹ́, pẹ̀lú omi, àti òwú òdòdó, àti ewé hísọ́pù ó sì fi wọ́n àti ìwé páàpáà àti gbogbo ènìyàn.

20. Wí pé, “Èyí ní ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run paláṣẹ fún yín.”

21. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n àgọ́, àti gbogbo ohun èlò ìsìn.

22. Ó sì fẹ́rẹ̀ jẹ́ ohun gbogbo ni a fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀nù gẹ́gẹ́ bí òfin; àti pé láìsí ìtàjẹ̀sílẹ̀ kò sí ìdáríjì.

Àwọn Hébérù 9