13. Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti akọ màlúù àti eerú ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí a ti sọ di aláìmọ́ ba ń sọni-di-mímọ́ fún ìwẹ̀nùmọ́ ara:
14. Mélòómélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kírísítì, ẹni, nípa Ẹ̀mí ayérayé, tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ sí Ọlọ́run láìní àbàwọ́n, yóò wẹ èérí ọkàn yín nù kúrò nínú òkú iṣẹ́ láti sin Ọlọ́run alààyè?
15. Àti nítorí èyí ni ó ṣe jẹ́ alárinà májẹ̀mú tuntun pé bí ikú ti ń bẹ fún ìdáǹdè àwọn ìrékọjá ti o tí wà lábẹ́ májẹ̀mú ìṣáájú, kí àwọn tí a ti pè lè rí ilèrí ogún àìnípẹ̀kun gbà.
16. Nítorí níbi tí ìwé ogún bá gbé wà, ikú ẹni tí o ṣe é kò lè ṣe àìsí pẹ̀lú;
17. Nítorí ìwé ogún ní agbára lẹ̀yìn ìgbà tí ènìyàn bá kú: Nítorí kò ní agbára rárá nígbà tí ẹni tí o ṣè e bá ń bẹ láàyè.