Àwọn Hébérù 8:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nísinsin yìí, kókó ohun tí à ń sọ nìyí: Àwá ní irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀, tí ó jokòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ ọla ńlá nínú àwọn ọ̀run:

2. Ìránṣẹ́ ibi mímọ́, àti ti àgọ́ tóòtọ́, tí Olúwa pa, kì í ṣe ènìyàn.

Àwọn Hébérù 8