Àwọn Hébérù 11:18-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nípa ẹni tí wí pé, “Nínú Ísáákì ni a o ti pé irú ọmọ rẹ̀:”

19. Ó sì rò ó si pé Ọlọ́run tilẹ̀ lè gbé e dìdè kúrò nínú òkú, bẹ́ẹ̀ ni, bí a bá sọ ọ lọ́nà àpẹẹrẹ, ó gbà á padà.

20. Nípa ìgbàgbọ́ ní Ísáákì súre fún Jákọ́bù àti Ísọ̀ níti ohun tí ń bọ̀.

21. Nípa ìgbàgbọ́ ni Jákọ́bù, nígbà ti o ń ku lọ, ó súrre fún àwọn ọmọ Jósẹ́fù ni ìkọ̀ọ̀kan; ó sì sìn ní ìtẹriba lé orí ọ̀pá rẹ̀.

22. Nípa ìgbàgbọ́ ni Jósẹ́fù, nígbà tí ó ń ku lọ, ó rántí ìjáde lọ àwọn ọmọ Ísraẹ́lì; ó sì pàṣẹ níti àwọn egungun rẹ̀.

Àwọn Hébérù 11