Ámósì 8:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run fi hàn mi: agbọ̀n èso pípọ́n.

2. Ó béèrè pé, “Ámósì kí ni ìwọ rí.”Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso pípọ́n.”Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Àsìkò náà pọ́n tó fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì; Èmi kì yóò dá wọn sí mọ́.”

3. Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Ní ọjọ́ náà, àwọn orin tẹ́ḿpìlì yóò yí padà sí ohùnréré ẹkún. Ọ̀pọ̀, àní ọ̀pọ̀ ara òkú-ni yóò wà ni ibi gbogbo! Àní ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́!”

4. Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń tẹ aláìní lórí ba,tí ẹ sì ń sọ talákà di ilẹ

5. Tí ẹ ń wí pé,“Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò paríkí àwa bá à lè ta ọkàkí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópinkí àwa bá à le ta jéró?”Kí a sì dín ìwọ̀n wa kùkí a gbéraga lórí iye tí a ó tà ákí a sì fi òṣùnwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ

6. Kí àwa lè fi fàdákà ra àwọn talákàkí a sì fi bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì ra aláìníkí a sì ta jéró tí a kó mọ́ ilẹ̀

7. Olúwa ti fi ìgbéraga Jákọ́bù búra pé: “Èmi kì yóò gbàgbé ọkan nínú ohun tí wọ́n ṣe.

8. “Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kì yóò ha wárìrì fún èyí?Àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ kì yóò ha sọ̀fọ̀?Gbogbo ilẹ̀ yóò ru sókè bí omi Náílì,yóò sì ru ú sókè pátapáta bí ìkún omia ó sì tì í jáde, a ó sì tẹ̀ ẹ́ rì gẹ́gẹ́ bí odò Éjíbítì.

Ámósì 8