8. yóò sì gbá rìẹrìẹ dé Júdà, a gba orí ẹ̀ lọ,yóò gba ibẹ̀ lọ yóò sì mú un dọ́run.Ìyẹ́ apá rẹ̀ tí ó nà yóò bo gbogbo ìbú ilẹ̀ náàÌwọ Ìmánúẹ́lì.
9. Ké ariwo ogun, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí a sì fọ́ọ yín túútúúú,fetísílẹ̀, ẹ̀yin ilẹ̀ jínjìn réré.Ẹ palẹ̀mọ́ fún ogun, kí a sì fọ́ ọ túútúúú!
10. Ẹ hun ète yín, yóò di títúká.Ẹ gbérò ètò náà, ṣùgbọ́n kì yóò dúró,nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lúu wa.
11. Olúwa bá mi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ lórí mi pẹ̀lú ìkìlọ̀ fún mi pé, èmi kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ó wí pé:
12. “Má ṣe pe éyí ní ọ̀tẹ̀ohun gbogbo tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá pè ní ọ̀tẹ̀,má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n bá bẹ̀rù,má sì ṣe fòyà rẹ̀.