4. Sọ fún un, ‘Ṣọ́ra à rẹ, fi ọkàn balẹ̀, kí o má ṣe bẹ̀rù. Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítoríi kùkùté igi ìdáná méjèèjì yìí, nítorí ìbínú gbígbóná Résínì àti Árámù àti ti ọmọ Rẹ̀málíà.
5. Árámù, Éfáímù àti Rèmálíà ti dìtẹ̀ ìparun rẹ, wọ́n wí pé,
6. “Jẹ́ kí a kọlu Júdà; jẹ́ kí a fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kí a sì pín in láàrin ara wa, kí a sì fi ọmọ Tábẹ́lì jọba lóríi rẹ̀.”
7. Ṣíbẹ̀ èyí ni ohun tí Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí:“ ‘Èyí kò ní wáyéÈyí kò le ṣẹlẹ̀,
8. nítorí Dámásíkù ni orí Árámù,orí Dámásíkù sì ni Résínì.Láàrin ọdún márùnlélọ́gọ́taÉfáímù yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́.
9. Ṣamaríà ni orí fún Éfáímù,ẹni tí ó sì jẹ́ orí Samaríà náà ni ọmọ Rèmálíà.’ ”
10. Bákan náà Olúwa tún bá Áhásì sọ̀rọ̀,