9. Èmi yóò mú ìrandíran wá láti ìdílé Jákọ́bù,àti láti Júdà àwọn tí yóò jogún òkè ńlá mi wọ̀n ọn nì;àwọn àyànfẹ́ ènìyàn mi yóò jogún wọn,ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ mi yóò sì gbé.
10. Ṣárónì yóò di pápá oko fún ọ̀wọ́ ẹran,àti àfonífojì Ákò yóò di ibi ìsinmi fún agbo ẹran,fún àwọn ènìyàn mi tí ó wá mi.
11. “Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó kọ Olúwa sílẹ̀tí ẹ sì gbàgbé òkè mímọ́ mi,tí ó tẹ́ tábìlì fún ọrọ̀tí ẹ sì kún abọ́ pẹ̀lú ọtí wáìnì fún àtubọ̀tán,
12. Èmi yóò yà ọ́ ṣọ́tọ̀ fún idà,àti pé ẹ̀yin yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ fún àwọn tí a pa;nítorí mo pè, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò dáhùn.Mo ṣọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò tẹ́tísílẹ̀Ẹ̀yin ṣe búrurú ní ojú miẹ sì yan ohun tí ó bàmí lọ́kàn jẹ́.”