Àìsáyà 65:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. wọ́n ń jókòó láàrin ibojìwọ́n sì ń lo òru wọn nínú ìṣọ́ ìkọ̀kọ̀;tí wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,tí ìkòkò ọbẹ̀ wọn kún fún ẹran àìmọ́;

5. tí ó wí pé, ‘Ẹ sún mẹ́yìn; ẹ má wá sọ́dọ̀ mi,nítorí mo ti jẹ́ mímọ́ jù fún un yín!’Àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èéfín nínú ihò imú miiná tí ń fi gbogbo ọjọ́ jó.

6. “Kíyèsí i, a ti kọ ọ́ síwájúu mi:Èmi kì yóò dákẹ́, ṣùgbọ́n n ó san ánpadà lẹ́kùn ún rẹ́rẹ́;Èmi yóò san án padà ní itan wọn

7. àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín àti tàwọn baba yín,”ni Olúwa wí.“Nítorí pé wọ́n sun ẹbọ ní orí òkè ńláwọ́n sì ṣe mí lẹ́gbin ní òkè kékeré,Èmi yóò wọ́n ọ́n sí wọn nítanẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀san ohun gbogbo tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀.”

8. Ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí òjé sì tún wà nínú àpólà gírépùtí àwọn ènìyàn sì wí pé, ‘má ṣe bà á jẹ́,ohun dáradára sì kù sínú rẹ̀,’bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe nítorí ìránṣẹ́ mi;Èmi kì yóò pa gbogbo wọn run.

9. Èmi yóò mú ìrandíran wá láti ìdílé Jákọ́bù,àti láti Júdà àwọn tí yóò jogún òkè ńlá mi wọ̀n ọn nì;àwọn àyànfẹ́ ènìyàn mi yóò jogún wọn,ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ mi yóò sì gbé.

10. Ṣárónì yóò di pápá oko fún ọ̀wọ́ ẹran,àti àfonífojì Ákò yóò di ibi ìsinmi fún agbo ẹran,fún àwọn ènìyàn mi tí ó wá mi.

Àìsáyà 65