3. Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ Olúwa,adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ.
4. Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro.Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfísíbà,àti ilẹ̀ rẹ ní Béúlà;nítorí Olúwa yóò yọ́nú sí ọàti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó.
5. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwóbẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwóGẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lóríì rẹ.
6. Èmi ti fi olùṣọ́ ránṣẹ́ sórí odi rẹ ìwọ Jérúsálẹ́mù;wọn kì yóò lè dákẹ́ tọ̀sán tòru.Ẹ̀yin tí ń ké pe Olúwa,ẹ má ṣe fún ra yín ní ìsinmi,