Àìsáyà 61:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ̀mí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà lára minítorí Olúwa ti fi àmì-òróró yàn míláti wàásù ìhìnrere fún àwọn talákà.Ó ti rán mi láti ṣe àwòtan oníròbìnújẹ́láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùnàti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,

2. Láti kéde ọdún ojúrere Olúwaàti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,

3. àti láti pèṣè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Ṣíhónìláti dé wọn ládé ẹ̀yẹ dípò eérú,òróró ìdùnnú dípò ìbànújẹ́,àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúùru ọkàn.A ó sì pè wọ́n ní óákù òdodo,irúgbìn Olúwaláti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.

4. Wọn yóò tún àwọn ahoro ìṣẹ̀ǹbáyé kọ́wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́tijọ́ náà bọ̀ sípò;wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padàtí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.

Àìsáyà 61