1. “Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,ògo Olúwa sì ràdọ̀bò ọ́.
2. Kíyèsí i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayéòkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn,ṣùgbọ́n Olúwa ràn bò ọ́ògo rẹ̀ sì farahàn lóríi rẹ.
3. Àwọn orílẹ̀ èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ,àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ.