Àìsáyà 6:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Lẹ́yìn náà, ọ̀kan nínú àwọn Ṣéráfù wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ́-iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní oríi pẹpẹ.

7. Èyí ni ó fi kàn mí ní ẹnu tí ó sì wí pé, “Wòó, èyí ti kan ètè rẹ; a ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.”

8. Lẹ́yìn náà, mo sì gbọ́ ohùn Olúwa wí pé, “Ta ni n ó rán? Ta ni yóò sì lọ fún wa?”Èmi sì wí pé, “Èmi nìyí, rán mi!”

9. Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn mi lọ kí o sì wí pé;“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;ní rírí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’

10. Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì,mú kí wọn kútíkí o sì pa ojú wọn dé.Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò fi ojú u wọn ríran,ki wọn má ba à fi etíi wọn gbọ́ràn,kí òye máa ba à yé wọn ní ọkàn an wọnkí wọn má ba à yípadà kí a má ba à sì wò wọ́n sàn.”

Àìsáyà 6