Àìsáyà 59:5-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Wọn ń pa ẹyín pamọ́lẹ̀wọn sì ń ta owú aláǹtakùn.Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹyin wọn yóò kú,àti nígbà tí a pa ọ̀kan, pamọ́lẹ̀ ni ó jáde.

6. Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán;wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn.Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdàkú sì kún ọwọ́ wọn.

7. Ẹsẹ̀ wọn yára bọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀;wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.Èrò wọn sì jẹ́ èrò ibi;ìparun àti ìdahoro ni ó wà ní ṣíṣe àmì ọ̀nà wọn.

8. Ọ̀nà àlàáfíà èyí ni wọn kò mọ̀;kò sí òdodo ní ojú ọ̀nà wọnwọ́n ti sọ wọ́n dì ọ̀nà kọ́rọkọ́rọ,kò sí ẹni tí ó tọ ọ̀nà yìí tí yóò rí àlàáfíà.

9. Nítorí èyí ni ẹ̀tọ́ fi jìnnà sí wa,àti tí òdodo kò fi tẹ̀wá lọ́wọ́.A ń wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ jẹ́ òkùnkùn;fún ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n à ń rìn nínú òjìji.

10. Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògirití a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú.Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni;láàrin alágbára àwa dàbí òkú.

Àìsáyà 59