Àìsáyà 58:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. “Bí ìwọ bá pa ẹṣẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú bíba ọjọ́-ìsinmi jẹ́,àti síse bí ó ti wù ọ́ ni ọjọ́ mímọ́ mi,bí ìwọ bá pe ọjọ-ìsinmi ní ohun dídùnàti ọjọ́ mímọ́ Olúwa ní ohun ọ̀wọ̀àti bí ìwọ bá bu ọlá fún un láti máa bá ọ̀nà tìrẹ lọàti láti má ṣe bí ó ti wù ọ́ tàbíkí o máa ṣọ̀rọ̀ òòrayè,

14. nígbà náà ni ìwọ yóò ní ayọ̀ nínú Olúwa rẹ,èmi yóò sì jẹ́ kí ìwọ kí ó máa gun ibi gíga ilẹ̀ ayé,àti láti máa jàdídùn ìní tiJákọ́bù baba rẹ.”Ẹnu Olúwa ni ó ti sọ̀rọ̀.

Àìsáyà 58