Àìsáyà 58:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Kígbe rẹ̀ ṣókè, má ṣe fà ṣẹ́yìn.Gbé ohùn rẹ ṣókè bí i ti fèrè.Jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún áwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọnàti fún ilé Jákọ́bù ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

2. Nítorí ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n ń wá mi kiri;wọ́n ṣe bí ẹni ní ìtara láti mọ ọ̀nà mi,àfi bí ẹni pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀ èdè kan tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nàtí òun kò sì tí ì kọ àṣẹ Ọlọ́run rẹ̀.Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ mi fún ìpinnu nìkanwọ́n sì ṣe bí ẹni ń tara fún Ọlọ́run láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn.

Àìsáyà 58