Àìsáyà 50:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Mo sí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí,àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irúngbọ̀n mi;Èmi kò fi ojú mi pamọ́kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọsùtì sí.

7. Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ràn mí lọ́wọ́;A kì yóò dójú tìmí.Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí Òkúta akọèmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.

8. Ẹni tí ó dámiláre wà nítòsí.Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀ṣùn kàn mí?Jẹ́ kí a kojú ara wa!Ta ni olùfisùn mi?Jẹ́ kí ó kòmí lójú!

9. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó ń ràn mí lọ́wọ́.Ta ni ẹni náà tí yóò dámí lẹ́bi?Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ;kòkòrò ni yóò sì mú wọn jẹ.

Àìsáyà 50