5. Ní ìsinsìn yìí, èmi yóò sọ fún ọohun tí n ó ṣe sí ọgbà-àjàrà mi:Èmi yóò gé igi inú un rẹ̀ kúrò,a ó sì pa á run,Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
6. Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoroláì kọ ọ́ láì rò ó,ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀.Èmi yóò sì pàṣẹ fún kùrukùruláti má ṣe rọ̀jò sóríi rẹ̀.”
7. Ọgbà-àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogunni ilé Ísírẹ́lìàwọn ọkùnrin Júdàsì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀.Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọn, ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni ó rí,Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ ẹkún ìpayínkeke.
8. Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́létí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kùtí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀.