29. Bíbú wọn dàbí tí kìnnìhún,wọ́n bú bí ẹgbọ̀rọ̀ kìnnìhún,wọ́n ń kọ bí wọ́n ti di ẹranànjẹ wọn mútí wọn sì gbé e lọ láìsí ẹni tí yóò gbà á là.
30. Ní ọjọ́ náà, wọn yóò hó lé e lórígẹ́gẹ́ bí i rírú omi òkun.Bí ènìyàn bá sì wo ilẹ̀,yóò rí òkùnkùn àti ìbànújẹ́;pẹ̀lúpẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn pẹ̀lú kùrukùru rẹ̀.