Àìsáyà 47:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Olùràpadà wa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀òun ni Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì.

5. “Jókòó ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, lọ sínú òkùnkùn,ọmọbìnrin àwọn ará Bábílónì;a kì yóò pè ọ́ ní ọbabìnrinàwọn ilẹ̀-ọba mọ́.

6. Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mití mo sì ba ogún mi jẹ́;Mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́,Ìwọ kò sì síjú àánú wò wọ́n.Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lúní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé.

7. Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀ṣíwájú títí láé—ọba-bìnrin ayérayé!’Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsí nǹkan wọ̀nyítàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.

8. “Nísinsìn yìí, tẹ́tísílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dátí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹtí o sì ń sọ fún ara rẹ pé,‘Èmi ni, kò sì sí ẹlòmìíràn lẹ́yìn mi.Èmi kì yóò di opótàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’

9. Méjèèjì yìí ni yóò wá sóríì rẹláìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà:pípàdánù ọmọ àti dídi opó.Wọn yóò wá sóríì rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹàti àwọn èpè rẹ tí kì í ṣélẹ̀.

Àìsáyà 47