5. “Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba?Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mití àwa yóò jọ farawéra?
6. Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọnwọ́n sì wọn fàdákà lórí òṣùwọ̀n;wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà,wọn sì tẹríba láti sìn ín.
7. Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n,wọ́n sì gbé e sí àye rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí.Láti ibẹ̀ náà kò le è paradàBí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn;òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀.
8. “Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ,fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀.
9. Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́tijọ́;Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlọ̀mìíràn;Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmìíràn bí ì mi.