13. Èmi yóò gbé Kírúsì ṣókè nínú òdodo mi:Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.Òun yóò tún ìlú mi kọ́yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀,ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan,ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
14. Ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Àwọn èròjà ilẹ̀ Éjíbítì àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kúṣì,àti àwọn Ṣábíáṣì—wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹwọn yóò sì jẹ́ tìrẹ;wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn,wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́.Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀,wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé,‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì sí ẹlòmìíràn;kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ”
15. Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́,Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Ísírẹ́lì
16. Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tìwọn yóò sì kan àbùkù;gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.
17. Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ni a ó gbàlà láti ọwọ́ OlúwaPẹ̀lú ìgbàlà ayérayé;a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójú tì yín,títí ayé àìnípẹ̀kun.