Àìsáyà 44:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹàti àwọn odò ni ilẹ̀ gbígbẹ;Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ,àti ìbùkún mi sóri àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ.

4. Wọn yóò dàgbà ṣókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínúpápá oko tútù,àti gẹ́gẹ́ bí igi póǹpóla léti odò tí ń sàn.

5. Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti Olúwa’;òmìíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jákọ́bù;bẹ́ẹ̀ ni òmìíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, Ti Olúwa,yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Ísírẹ́lì.

Àìsáyà 44