Àìsáyà 43:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Èyí ni ohun tí Olúwa wíolùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì;“Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Bábílónìláti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá,gbogbo ará Bábílónìnínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.

15. Èmi ni Olúwa, Ẹni Mímọ́ rẹ,Ẹlẹ́dàá Ísírẹ́lì, ọba rẹ.”

16. Èyí ni ohun tí Olúwa wíẸni náà tí ó la ọ̀nà nínú òkun,ipa-ọ̀nà láàrin alagbalúgbú omi,

17. ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde,àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀,wọ́n sì ṣùn ṣíbẹ̀, láìní lè dìde mọ́,wọ́n kú pirá bí òwú fìtílà:

Àìsáyà 43