4. Lẹ́yìn náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Àìṣáyà wá pé
5. “Lọ kí o sì sọ fún Heṣekáyà pé, ‘Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Ọlọ́run Dáfídì baba rẹ sọ pé: Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ; Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀dógún kún ọjọ́ ayé rẹ.
6. Èmi yóò sì gba ìwọ àti ìlú yìí sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọba Áṣíríà. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí.
7. “ ‘Èyí yìí ni àmì tí Olúwa fún ọ láti fi hàn wí pé Olúwa yóò mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ:
8. Èmi yóò mú òjìji òòrùn kí ó padà ṣẹ́yìn ní ìsísẹ̀ mẹ́wàá nínú èyí tí ó fi ṣọ̀kalẹ̀ ní ibi àtẹ̀gùn ti Áhásì.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni òòrùn padà ṣẹ́yìn ní ìsíṣẹ̀ mẹ́wàá sí ibi tí ó ti dé tẹ́lẹ̀.
9. Ìwé tí Heṣekáyà ọba Júdà kọ lẹ́yìn àìṣàn rẹ̀ nígbà tí ó ti gbádùn tán: