Àìsáyà 37:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ọba Heṣekáyà gbọ́ èyí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara rẹ̀, ó sì wọ inú tẹ́ḿpìlì Olúwa lọ.

2. Òun sì rán Eliákímù alákoṣo ààfin, Ṣébínà akọ̀wé, àti aṣíwájú àwọn àlùfáà, gbogbo wọn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì.

3. Wọ́n sọ fún un pé, “Báyìí ni Heṣekáyà sọ: ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ ìbànújẹ́, ìbáwí àti ìtìjú gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ọmọdé kùdẹ̀dẹ̀ ìbí tí kò sì sí agbára láti bí wọn.

Àìsáyà 37