1. Nígbà tí ọba Heṣekáyà gbọ́ èyí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara rẹ̀, ó sì wọ inú tẹ́ḿpìlì Olúwa lọ.
2. Òun sì rán Eliákímù alákoṣo ààfin, Ṣébínà akọ̀wé, àti aṣíwájú àwọn àlùfáà, gbogbo wọn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì.