Àìsáyà 36:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Eliákímù ọmọ Hílíkáyà alábojútó ààfin, Ṣébínà akọ̀wé, àti Jóà ọmọ Áṣáfù akọ̀wé jáde lọ pàdé rẹ̀.

4. Ọ̀gágun náà sọ fún wọn wí pé, “Ẹ sọ fún Heṣekáyà,“ ‘Èyí yìí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Áṣíríà sọ pé: Lóríi kí ni ìwọ gbé ìgbẹ́kẹ̀lé tìrẹ yìí lé?

5. Ìwọ sọ wí pé ìwọ ní ète àti agbára ogun—ṣùgbọ́n ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ aṣán. Ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tí ìwọ fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi?

6. Wò ó nísinsìn yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé Éjíbítì ẹ̀rúnrún igi ọ̀pá lásán tí í gún ni lọ́wọ́ tí í sìí dọ́gbẹ́ sí ni lára tí a bá gbára lé e! Bẹ́ẹ̀ ni Fáráò ọba Éjíbítì sí àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e.

Àìsáyà 36