Àìsáyà 3:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Nítorí náà Olúwa yóò mú egbòwá sórí àwọn obìnrin Ṣíónì, Olúwa yóò sì pá wọn ní agbárí.”

18. Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti ìgbàrí àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá

19. gbogbo yẹtí, ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú,

20. gbogbo gèlè ìwégbà ọrùn ẹ̀ṣẹ̀ àti àyà, àwọn ìgo tùràrí àti òògùn,

Àìsáyà 3