Àìsáyà 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Kíyèsí i, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,fẹ́ mú ìpèsè àti ìrànlọ́wọ́ kúrò ní Jérúsálẹ́mù àti Júdàgbogbo ìpèsè ounjẹ àti ìpèsè omi

2. àwọn akíkanjú àti jagunjagun,adájọ́ àti wòlíì,aláfọ̀sẹ àti alàgbà,

3. balógun àádọ́ta àti bọ̀rọ̀kìnní ènìyàn,olùdámọ̀ràn, oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́àti ògbójú oníṣegùn.

4. Èmi ó sọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin di aláṣẹ wọn,ọ̀dọ́mọdé lásán làsàn ni yóò sìmáa jọba lóríi wọn.

Àìsáyà 3