Àìsáyà 27:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò fi idà rẹ̀ jẹni níyàidà rẹ̀ amúbí-iná tí ó tóbi tí ó sì lágbáraLẹ́fíátanì ejò tí ń yọ̀ tẹ̀ẹ̀rẹ̀ n nì,Lẹ́fíátanì ejò tí ń lọ́ bìrìkìtì;Òun yóò sì pa ewèlè inú òkun náà.

2. Ní ọjọ́ náà“Kọrin nípa ọgbà-àjàrà eléso kan.

3. ÈMI Olúwa ń bojú tó o,Mo ń bomirin ín láti ìgbàdégbà.Mò ń sọ́ ọ tọ̀sán tòrukí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára.

4. Inú ò bí mi.Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí!Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun;Èmi yóò sì dáná ṣun gbogbo wọn.

5. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò;jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lúu mi,bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lúu mi.”

Àìsáyà 27