Àìsáyà 26:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ṣùgbọ́n àwọn òkúu yín yóò wà láàyèara wọn yóò dìde.Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀,dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀.Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀,ayé yóò bí àwọn òkúu rẹ̀ lọ́mọ.

20. Ẹ lọ, ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ wọ ìyẹ̀wùu yín lọkí ẹ sì ti àwọn ìlẹ̀kùn lẹ́yìn in yín,ẹ fi ara yín pamọ́ fún ìgbà díẹ̀títí tí ìbínú un rẹ̀ yóò fi rékọjá.

21. Kíyèsíì, Olúwa ń jáde bọ̀ láti ibùgbé e rẹ̀láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé níìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ẹ wọn.Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí oríi rẹ̀,kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́.

Àìsáyà 26