Àìsáyà 23:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Olúwa ti na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde sí orí òkunó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Fonísíàpé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run.

12. Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́”ìwọ wúndíá ti Ṣídónì, tí a ti tẹ̀rẹ́ báyìí!“Gbéra, rékọjá lọ sí Ṣáípúrọ́sì,níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.”

13. Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì,àwọn ènìyàn tíkò jámọ́ nǹkankan bàyìíÀwọn Ásíríà ti sọ ọ́ diibùgbé àwọn ohun abẹ̀mí ihà;wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gun wọn ṣókè,wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòòhòwọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.

14. Pohùnréré, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Táṣíṣì;wọ́n ti pa odi rẹ̀ run!

15. Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tírè fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tírè gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè:

16. “Mú hápù kan, rìn kọjá láàrin ìlú,Ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé;lu hápù rẹ dáadáa, kọ ọ̀pọ̀ orin,kí a lè ba à rántíi rẹ.”

Àìsáyà 23