Àìsáyà 23:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Tírè:Pohùnréré, ìwọ ọkọ̀-ojú omi Táṣíṣì!Nítorí a ti pa Tírè runláìsí ilé tàbí èbúté.Láti ilẹ̀ Ṣáípúrọ́sì niọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn.

2. Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣùàti ẹ̀yin oníṣòwò ti Sídónì,ẹ̀yin tí àwọn awẹ̀kun ti sọ dọlọ́rọ̀.

3. Láti orí àwọn omi ńláni irúgbìn oníhóró ti ilẹ̀ Ṣíhórì ti wáìkóórè ti Náì ni owóòná Tírè,òun sì ti di ibùjókòó ọjà fúnàwọn orílẹ̀ èdè.

Àìsáyà 23