Àìsáyà 10:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrin àwọn ìgbèkùntàbí kí o ṣubú sáàrin àwọn tí a pa.Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò,ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè.

5. “Ègbé ni fún àwọn ará Ásíríà, ọ̀gọ ìbínú mi,ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà!

6. Mo rán an sí orílẹ̀ èdè aláìní Ọlọ́runMo dojúu rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó múmi bínúláti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógunláti tẹ̀mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.

7. Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe,èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn;èrò rẹ̀ ni láti parun,láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè.

Àìsáyà 10